- Hadisi naa jẹ ipilẹ nibi alaye awọn ipo yiyi ibajẹ pada.
- Àṣẹ naa jẹ pẹlu díẹ̀ díẹ̀ nibi kikọ kuro nibi ibajẹ, gbogbo eniyan ni ibamu si odiwọn ini ikapa rẹ ati ini agbara rẹ ni.
- Kikọ kuro nibi ibajẹ jẹ abala kan ti o tobi ninu ẹsin ti ko bọ fun ẹnikẹni, ti a la a bọ Musulumi kọ̀ọ̀kan lọrun ni ibamu si ikapa rẹ.
- Pipaṣẹ ohun rere ati kikọ kuro nibi ibajẹ wa ninu iwa igbagbọ, ati pe igbagbọ maa n lekun o si maa n dinku.
- Wọn ṣe ni majẹmu nibi kikọ kuro nibi ibajẹ: Imọ nipa pe ki ìṣẹ́ yẹn jẹ ibajẹ.
- Wọn ṣe ni majẹmu nibi yiyi ibajẹ pada: Ki ibajẹ ti o tobi ju ìyẹn lọ ma jẹ yọ latara rẹ̀.
- Àwọn ẹkọ ati awọn majẹmu n bẹ fun kikọ kuro nibi ibajẹ ti o lẹtọọ fun musulumi lati kọ wọn.
- Kíkọ ibajẹ bukaata si òṣèlú ti o ba sharia mu, ati imọ ati amọdaju.
- Aikọ ibajẹ pẹlu ọkan n tọka sí lilẹ igbagbọ.