Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ; ìyẹn ni pe ẹni ti n ki...
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀y...
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oo...
Lati ọdọ Abu Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ nin...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- beere lọwọ awọn saabe rẹ pé: . Njẹ ẹ fẹ ki n fun yin ni iro ki n si kọ yin ni eyi ti o daa julọ ninu awọn...
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀,...
Nínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni t...
Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbi...
Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe: Awọn gbolohun kan wa fun wíwá idarijin, ati pe eyi ti o dara ju ti o si tobi ju ninu wọn ni ki...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”.

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))

Lati ọdọ Abu Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin ti o si loore julọ fun yin ju nina wura ati fadaka lọ, ti o si loore julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Wọn sọ pé: Bẹẹni. O sọ pe: "Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-".

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹyin naa o maa fi méjèèjì pa ibi ti o ba ṣeé pa ni ara rẹ, o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ ati oju rẹ, ati ẹ̀yà ti iwájú ninu ara rẹ, o maa ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹẹmẹta.

Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».

Láti ọ̀dọ̀ Samurah ọmọ Jundub- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”.

Lati ọdọ Abu Ayyuub- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaao da gẹgẹ bii ẹni ti o sọ ẹrú mẹrin ninu ọmọ Ismail di olómìnira”.

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì ni: SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII”.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”.

Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”.