- Dajudaju idunnimọ iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni gbangba ati kọ̀rọ̀ wa ninu awọn eyi ti o tobi julọ ninu asunmọ, ati eyi ti o ṣe anfaani julọ lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Gbogbo awọn iṣẹ wọn ṣe wọn lofin fun igbe iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- dúró ni, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi). Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Dajudaju wọn ṣe tawaaf ati sisa safa ati mariwa, ati jiju oko lofin lati fi gbe ìrántí Ọlọhun duro ni. Abu Daud ati Tirmidhi ni wọn gba a wa.
- Al-'Izzu ọmọ Abdus-Salaam sọ ninu tira rẹ ti o n jẹ AL-QAWAA’ID pé: Hadiisi yii wa ninu nnkan ti o tọka si pe ẹsan ko da lori odiwọn wahala nibi gbogbo awọn ijọsin, bi ko ṣe pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- le sẹsan lori iṣẹ kekere ju ńlá lọ, ẹsan maa n da lori ìyàtọ̀ ni ipo nibi iyi.
- Al-Manawi sọ ninu Fayd al-Qadeer pe: Wọn tumọ Hadith yii si pe iranti dara julọ fun awọn ti wọn n ba sọrọ pẹ̀lú rẹ, ti wọn ba fi ba akin èèyàn ti o maa wúlò fun Isilaamu ni oju ogun sọ̀rọ̀, wọn maa sọ fun un pe jijagun ni, tabi ọlọrọ ti owo rẹ maa ṣe anfaani fun talika, wọn maa sọ fun un pe saara ni, àti ẹni ti o ni ikapa láti ṣe hajj, wọn maa sọ fun un pe hajj ni, tabi ẹni tí o ni obi mejeeji, wọn maa sọ fún un pé ṣíṣe dáadáa si awọn mejeeji ni, pẹ̀lú rẹ ni ibaramu ṣe maa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn hadith oríṣiríṣi naa.
- Eyi ti o pe julọ ninu iranti ni èyí tí ahọn pe pẹlu ironusi i pẹlu ọkan, lẹyin naa ni eyi ti o wáyé pẹlu ọkan nìkan ṣoṣo gẹgẹ bii ìrònú, lẹyin naa ni eyi ti o waye pẹlu ahọn nikan ṣoṣo, ati pe ẹsan n bẹ nibi ọkọọkan ti Ọlọhun ba fẹ.
- Ki Musulumi dunni mọ awọn iranti ti wọn so pọ mọ awọn isẹsi gẹgẹ bii awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ, ati wiwọnu mọsalasi, ati ile ati ile ẹgbin ati jijade kuro nibẹ.... Ati eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn maa jẹ ki o wa ninu awọn oluranti Ọlọhun lọpọlọpọ igba.