- Imọra pin si meji: Imọra ti ita, o maa waye pẹlu aluwala ati iwẹ, ati imọra ti inú, o maa waye pẹlu imu Ọlọhun ni Ọkan ati igbagbọ ati iṣẹ oloore.
- Pataki mímú ojú tó irun ati pe o jẹ imọlẹ fun erusin Ọlọhun ni aye ati ọjọ igbedide.
- Saara ṣíṣe jẹ ẹri lori ododo igbagbọ.
- Pataki ṣíṣe iṣẹ pẹlu Kuraani ati gbigba a lododo lati le jẹ ẹri fun ẹ ti ko nii tako ẹ.
- Ẹmi ti o ko ba ko airoju ba a pẹlu itẹle yoo ko airoju ba ẹ pẹlu ẹṣẹ.
- Gbogbo eniyan dandan ni fun un pe ko ṣiṣẹ; ninu pe ki o bọ okun lọrun ara rẹ pẹlu itẹle tabi ki o ko iparun ba a pẹlu ẹṣẹ.
- Suuru ṣíṣe n bukaata si atẹmọra ati wiwa ẹsan ti ilekoko si n bẹ nibẹ.