Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun...
Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibò...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu t...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wípé dajudaju gbogbo Musulumi kọọkan ti o ba n ka harafi kan ninu tira Ọlọhun ni ẹsan kọọkan a máa bẹ fun...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Wọn maa sọ fun onikuraa...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé wọn maa sọ fun ẹni ti n ka Kuraani, ti n lo ohun ti o wa ninu rẹ, ti n dunni mọ́ ọn ni kíkà ati híhá,...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀san kika aaya mẹ́ta lori irun; o ni oore ju ki èèyàn o ri ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti...
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo,...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o...
Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wa pe àwọn maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ ti o wa ninu ẹ, wọn sọ pé: A wa kọ́ imọ ati iṣẹ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?” A sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: “Àwọn aaya mẹ́ta tí ọ̀kan nínú yín máa ń ka lori irun rẹ ni oore fun un ju ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra lọ”.
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.
Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.
Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Adua naa ni ìjọsìn”, lẹyin naa ni o wa ka: “{Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ} [Gaafir: 60]”.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”.