/ “Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”

“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”.
Al-Haakim ati At-Tọbarọọniy ni wọ́n gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ maa n gbo ni ọkan Musulumi o si maa n lẹ gẹgẹ bi aṣọ tuntun ti o maa n gbo ti wọn ba ti lo o fun ìgbà pípẹ́; Ati pe ìyẹn maa n ṣẹlẹ̀ pẹlu okunfa adinku nibi ijọsin, tabi dida awọn ẹṣẹ ati titẹri sinu awọn adun. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ́ wa sọna lati maa pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati maa sọ igbagbọ wa di tuntun, pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan ati pipọ ni iranti ati wiwa aforijin.

Hadeeth benefits

  1. Ṣíṣenilojukokoro lori bibeere ìdúróṣinṣin ati sisọ igbagbọ di tuntun ninu ọkan lọdọ Ọlọhun.
  2. Igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan, o maa n lekun pẹlu itẹle, ó si maa n dinku pẹlu ẹṣẹ.