- Ṣiṣe pipọ ni ijọsin ni ohun ti a fẹ ati kiki irun akigbọrẹ ninu ile.
- Irun kiki ko lẹtọọ ni awọn iboji; nitori pe o jẹ ọna kan ninu awọn ọna ti wọn maa n gba lati ṣe ẹbọ ati kikọja aala nipa awọn ti wọn wa nibẹ, yatọ si irun ti a maa n ki si oku lara.
- Kikọ kuro nibi kiki irun nibi awọn sàréè fi ẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn saabe, nitori idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ lati jẹ ki awọn ile da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ.