- Adua ni ipilẹ ìjọsìn, ko tọ́ ki a ṣe e fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun.
- Adua kó pàápàá ijẹ-ẹru sínú, ati jijẹwọ ọ̀rọ̀ Olúwa ati ikapa Rẹ, ati ìní bukaata ẹrú si I.
- Àdéhùn ìyà ti o le koko ni ẹsan ìgbéraga nipa jijọsin fun Ọlọhun ati gbigbe pipe E ju silẹ, ati pe awọn ti wọn n ṣe ìgbéraga nipa pipe Ọlọhun maa wọ iná Jahannamọ ni ẹni yẹpẹrẹ.