- Àlàyé ọla ti n bẹ fun kika Kuraani ni orí ìrun.
- Awọn iṣẹ rere ni oore, wọn ṣi tun maa ṣẹku titi láéláé ju igbadun ayé ti o maa tán lọ.
- Ọla yii kò mọ lori kika aaya mẹta nìkan, gbogbo ìgbà ti ẹni tí n kirun ba ti n ṣe alekun nibi kika àwọn aaya nibi irun rẹ ni ẹsan rẹ maa loore fun un ju iye onka wọn ninu ràkúnmí aboyún lọ.