- Ọla adua, ati pe ẹni ti o ba pe Ọlọhun ni o n gbe E tobi, ti o si n fi rinlẹ fun Un pe Ọlọ́rọ̀ ni, mimọ ni fun Un, èèyàn kii pe tálákà, Olùgbọ́ si ni, èèyàn kii pe odi, Ọlọ́rẹ ni, eeyan kii pe ahun, Aláàánú ni, èèyàn kii pe ẹni ti o le, Ọba ti O ni ikapa ni, èèyàn kii pe ẹni ti o kagara, Ọba ti O sunmọ ni, ẹni tí ó jìnnà ko lee gbọ, ati ohun ti o yatọ si ìyẹn ninu awọn ìròyìn títóbi ati ẹwà fun Ọlọhun, mimọ ni fun Un, Ọba ti ọla Rẹ ga.