Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ki a ma maa bú àwọn òkú, ati pe eyi wa ninu awọn iwa buruku; torí pé wọn ti de ibi ti nǹkan ti w...
Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ki Mùsùlùmí yan ọmọ-ìyá rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lodi kọjá ọjọ́ mẹ́ta, ti wọn maa pade ara wọn, ti wọn ko nii...
Lati ọdọ Sahl ọmọ Sahd - ki Ọlọhun yọnu si i - ó gba a wa lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pé ó sọ pé: "Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi d...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa awọn nkan meji tó ṣe pé tí Musulumi bá dúnní mọ́ wọn, dajudaju yóò wọ Alujanna. Ikinni: Ṣíṣ...
Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan: Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai s...
Láti ọ̀dọ̀ Usaamah ọmọ Zayd- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe oun ko fi àdánwò kan kan silẹ lẹ́yìn oun ti o ni àwọn ọkùnrin lára ju àwọn obìnrin lọ, ti o ba jẹ ọk...

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”

Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.

Lati ọdọ Sahl ọmọ Sahd - ki Ọlọhun yọnu si i - ó gba a wa lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pé ó sọ pé: "Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna".

Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ nkan mẹẹrin ni ẹnu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si jọ mi l'oju, o sọ pe: «Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ, ko si si aawẹ ni ọjọ meji: Itunu awẹ ati ileya, ko si tun si irun lẹyin asunbaa titi ti oorun o fi yọ, ko si si lẹyin Asri naa titi ti yio fi wọ, wọn o si tun gbọdọ di ẹru irin-ajo ayaafi lati lọ si masalasi mẹta: Masalasi abeewọ, ati masalasi aqsa, ati masalasi mi yii».

Láti ọ̀dọ̀ Usaamah ọmọ Zayd- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”.

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin, dajudaju akọkọ fitina awọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lara obinrin".

Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ko si igbeyawo kan afi pẹlu alaṣẹ obinrin”.

Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: ”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”.

Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ayé ìgbádùn ni, eyi ti o loore ju ninu ìgbádùn ayé ni obìnrin rere”

Lati ọdọ Abdur Rahmān ọmọ Abu Laylā o ni pe awọn wa ni ọdọ Hudhayfah, ni o ba beere fun omi, ni abọná kan ba fun un ni omi, nígbà tí o wa gbe ife omi yẹn fun un, o lẹ ẹ pada mọ ọn, o wa sọ pe: Ti kii ba ṣe pe mo ti kọ ọ fun un ni nkan ti kii ṣe ẹẹkan ti kii ṣe ẹẹmeji - bi ẹni ti n sọ pe: Mio ba ti ṣe nǹkan ti mo ṣe yii -, ṣugbọn mo gbọ ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin.

Lati ọdọ ọmọ ‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -: Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ nkan ti n jẹ al-Qaza‘ (ki èèyàn fá orí apakan ki o dá apakan sí).

Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ ge awọn tubọmu ki ẹ si da awọn irungbọn si”.