- Ṣiṣe wiwọ aṣọ alaari ni eewọ fun ọkunrin, ati adehun iya ti o le fun ẹni ti o ba wọ ọ.
- Wọn ṣe ni ẹtọ fun awọn obinrin ki wọn wọ aṣọ alaari.
- Ṣiṣe jijẹ ati mimu ninu abo wura ati fadaka ati ife wọn ni eewọ fun ọkunrin ati obinrin.
- Lile Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - nibi kikọ, o si sọ idi rẹ pe oun ti kọ fun un ni ọpọ igba kuro nibi lilo awọn igba wura ati fadaka, ṣugbọn ko jawọ.