- Aini ẹtọ ṣiṣe irin-ajo obinrin lai si eleewọ pẹlu rẹ.
- Obìnrin o kii ṣe eleewọ fun obinrin ni irin-ajo; fun gbolohun rẹ ti o sọ pe: “Ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ”.
- Gbogbo nkan ti wọn ba ti n pe ni irin-ajo, dajudaju wọn kọ fun obinrin ki o lọ lai si ọkọ tabi eleewọ pẹlu rẹ, ati pe hadīth yii nii ṣe pẹlu ìṣesí onibeere ati aaye rẹ.
- Eleewọ obinrin ni ọkọ rẹ tabi ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ ni eewọ fun un titi láéláé latari ìbátan gẹgẹ bii baba ati ọmọ ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya l'ọkunrin, tabi ifunlọyan gẹgẹ bii baba lati ibi ifunlọyan ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin lati ibi ifunlọyan, tabi ijẹ ana gẹgẹ bii baba ọkọ, ati pe yio jẹ musulumi ti o balaga ti o ni laakaye ti o ṣeé gbara le ti o ṣee fi ọkan tan, torí pé dajudaju nkan ti wọn gbero nibi eleewọ ni dida aabo bo obinrin ati sisọ ọ ati mimu ojú tó alamọri rẹ.
- Akolekan ofin Isilaamu pẹlu ọmọbinrin ati dida aabo bo o ati sisọ ọ.
- Aini alaafia kiki irun naafila lẹyin irun Al-fajri ati irun Asri, ati pe wọn yọ kuro ninu iyẹn ṣiṣe adapada awọn irun ọranyan ti o bọ, ati awọn irun ti o ni idi gẹgẹ bii tahiyyatul masjid (irun ti a maa n ki ti a ba wọ masalasi ki a to jokoo) ati eyi ti o jọ ọ.
- Irun kiki jẹ eewọ ni kete lẹyin yiyọ oorun, dipo bẹ́ẹ̀ o gbọdọ gbera soke ni odiwọn ọ̀kọ̀, ni nkan ti o sunmọ iṣẹju mẹwaa titi di bii iṣẹju mẹẹdogun.
- Asiko Asri gun titi di igba ti oorun o fi wọ.
- O n bẹ ninu rẹ ṣiṣe ni ẹtọ didi ẹru irin-ajo lọ si awọn masalasi mẹta.
- Ọla ti n bẹ fun awọn masalasi mẹtẹẹta naa lori awọn miran.
- Ailẹtọọ ṣiṣe irin-ajo lati lọ bẹ saare wo koda ko jẹ saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe ṣiṣe abẹwo rẹ (saare Anabi) tọ fun ẹni ti o wa ni Mẹdinah, tabi ẹni ti o wa si ibẹ fun idi kan ti wọn ṣe lofin tabi ti o lẹtọọ.