Lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ ki ọkunrin o maa wo ihoho ọkunrin, tabi ki obinrin o maa wo ihoho obinrin.
Ati pe nkan ti n jẹ ‘Aorah n...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii se ọlọ́rọ̀ burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀...
Ko si ninu ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o maa sọ̀rọ̀ buruku, tabi wu iwa burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e, o si jẹ oníwà ńlá.
Anọb...
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumin...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iwa rere maa mu ẹni tí n wù ú de ipo ẹni tí n dunni mọ́ aawẹ ni ọsan ati idide fun ìjọsìn ni oru,...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ì...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé èèyàn ti o pe julọ ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dáa, bíi títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ọ̀rọ̀ rere...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu èèyàn wọ alujanna méjì ni, àwọn naa ni:
Ipaya Ọlọhu...
Lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho ọkunrin, obinrin naa o si gbọdọ maa wo ihoho obinrin, ọkunrin o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu ọkunrin ninu asọ kan, obinrin naa o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu obinrin ninu asọ kan».
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii se ọlọ́rọ̀ burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ sọ ọrọ burúkú, o maa n sọ pe: “Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”.
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.
Sa‘d ọmọ Hishām ọmọ ‘Āmir sọ – nigba ti o wọlé tọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i pé-: Irẹ iya awa mu’mini, fun mi ni iro nipa iwa Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o sọ pe: Ṣe iwọ o ki n ka Alukurāni ni? Mo sọ pe: Mo maa n ka a, o sọ pe: Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani.
Lati ọdọ Shaddaad ọmọ Aos- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo há nǹkan méjì lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe: “Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan, ti ẹ ba ti fẹ pa nǹkan ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba ti fẹ du nǹkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin pọ́n ọ̀bẹ rẹ ki ó mú, ki o si tètè ko ìsinmi ba nǹkan ti o fẹ dú”.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì, àwọn ti wọn n ṣe deede nibi ìdájọ́ wọn, ati lọ́dọ̀ àwọn ará ilé wọn, ati nibi ohun ti n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn”.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Saheed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”.
Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ ẹni ti o gbe almisiki: Ninu ki o fun ọ nínú ẹ, tabi ninu ki o ra ọjà lọwọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o daa latara rẹ, ati pe ẹni ti o n fẹ iná alagbẹdẹ: Ninu ki o jo aṣọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o buru".
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Arákùnrin kan sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi, o sọ pé: “Ma ṣe maa binu”, o wa pààrà rẹ ni ọpọlọpọ ìgbà, o tun sọ pé: “Ma ṣe maa bínú”.