“Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé èèyàn ti o pe julọ ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dáa, bíi títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ọ̀rọ̀ rere, ati ki èèyàn má fi sùtá kan ẹlòmíràn.
Mumini ti o loore julọ ni àwọn ti wọn loore julọ fun awọn obinrin wọn, gẹgẹ bii ìyàwó rẹ, ati awọn ọmọbìnrin rẹ, ati awọn arábìnrin rẹ, ati awọn mọlẹbi rẹ lóbìnrin; torí pé àwọn ni wọn ni ẹtọ si iwa dáadáa ju ninu awọn èèyàn.
Hadeeth benefits
Ọla ti n bẹ fun iwa dáadáa, ati pe o wa ninu igbagbọ.
Iṣẹ wa ninu igbagbọ, igbagbọ maa n lékún, o si maa n dínkù.
Apọnle Isilaamu fun obìnrin, ati ṣisẹnilojukokoro lori ṣíṣe dáadáa si i.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others