- Idinamọ gbigba ẹsan pẹlu nǹkan ti o ju iru aburu ti wọn fi kan èèyàn lọ.
- Ọlọhun ko pa ẹrú Rẹ ni àṣẹ pẹlu nǹkan ti o maa ko ìnira ba wọn.
- Ṣíṣe ifi inira kan èèyàn ati gbigba ẹsan inira pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tabi ìṣe tabi gbigbe ju silẹ ni eewọ.
- Ẹsan maa wa latara ìran iṣẹ, ẹni ti o ba ko ìpalára ba ẹlòmíì, Ọlọhun maa ko ìpalára ba a, ẹni tí ó bá fi ara ni ẹlòmíì, Ọlọhun maa fi ara ni oun naa.
- Ọkan ninu awọn ofin Sharia ni pe: “A maa n mu ipalara kuro ni.” Sharia ko fi ọwọ́ si ipalara, o si kọ ipalara.