- Kikọ kuro nibi wiwo awọn ihoho yatọ si ọkọ ati iyawo rẹ.
- Isilaamu ṣẹni lojukokoro lori fifọ awujọ mọ ati titi ilẹkun awọn ọna ti o le ja si ibi awọn ibajẹ.
- Ṣiṣe lẹtọọ wiwo ihoho nigba ti bukaata ba pepe fun un gẹgẹ bii ṣiṣe ìwòsàn ati nkan ti o jọ ọ, pẹlu pe ki o jẹ èyí tí ko si adun nibẹ.
- Wọn pa musulumi l'aṣẹ pẹlu bibo ihoho rẹ ati rírẹ oju rẹ nilẹ kuro nibi ihoho ẹlòmíràn.
- Wọn s'ẹsa kikọ fún ọkunrin pẹlu ọkunrin ati obinrin pẹlu obinrin; nítorí pé o yara pepe lọ si'bi wiwo ati ṣiṣi awọn ihoho silẹ.