- Ikilọ kuro nibi ìbínú ati awọn okùnfà rẹ; tori pe oun ni o ko gbogbo aburu sinu, ṣiṣọra kuro nibẹ ni o ko gbogbo oore sínú.
- Ibinu nítorí Ọlọhun, gẹgẹ bii ibinu nígbà tí wọ́n bá rú òfin Ọlọhun, eyi wa lara ibinu ti o dára.
- Àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tí a bá nílò rẹ̀ títí tí olùgbọ́ yóò fi mọ̀ nípa rẹ̀ tí yóò sì mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀.
- Ọla ti n bẹ fun wíwá àsọtẹ́lẹ̀ lati ọdọ onimimọ.