Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe agbára gidi kii ṣe agbára ti ara, tabi ẹni ti o ba maa dá alágbára mìíràn mọ́lẹ̀. Alágbára ganga...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n ṣe wáàsí fun ọm...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n gba ọmọ-ìyá rẹ ni imọran pe ki o fi àpọ̀jù itiju silẹ! O wa ṣàlàyé fun un pe ìtìjú wa...
Lati ọdọ Al-Miqdam ọmọ Maadi Karib, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ...
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye ọkan lara awọn okunfa ti o lè fun ajọṣepọ ati ifẹ lagbara laarin awọn onigbagbọ ododo, òun naa ni...
Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Gbogbo dáadáa sàárà ni”.
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ar...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan l'ori gbogbo musulumi ti o ni iwọ ni ọrùn ni ojoojumọ pẹlu onka gbogbo ibi t...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú”.

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n ṣe wáàsí fun ọmọ-iya rẹ nipa ìtìjú, o wa sọ pé: “Itiju wa ninu igbagbọ”.

Lati ọdọ Al-Miqdam ọmọ Maadi Karib, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”.

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Gbogbo dáadáa sàárà ni”.

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ, gbogbo ọjọ ti oorun ba ti n yọ ti o ba n ṣe deede laarin eeyan meji saara ni, ati pe ki o ran ẹnikan lọwọ l'ori nkan ọ̀gùn rẹ, boya ki o gbe e gun un tabi ki o gbe ẹru rẹ fun un lori rẹ saara ni, ati pe ọrọ daadaa saara ni, ati gbogbo igbesẹ ti o ba n gbe lọ sí ibi irun saara ni, ki o si tun maa mu nkan ti o le ṣe eeyan ni ṣuta kuro l'ọna saara ni»

Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».

Lati ọdọ Abu Huraira, o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ".

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ki o yaa maa ṣe apọnle aládùúgbò rẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa ṣe apọnle àlejò rẹ”.

Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe: “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.

Láti ọ̀dọ̀ Jariir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”.

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».