- Tito awọn eegun ọmọ Anabi Ādam ati ini alaafia rẹ ninu awọn idẹra Ọlọhun ti o tobi julọ lori rẹ ni, nitori naa eegun kọọkan bukaata si saara fun un lati dupẹ idẹra yẹn.
- Ṣiṣenilojukokoro lori títún ọpẹ dú ni ojoojumọ fun aiduro awọn idẹra yẹn.
- Ṣiṣenilojukokoro lori idunimọ awọn naafila ati saara ni ojoojumọ.
- Ọla ti nbẹ fun ṣiṣe àtúnṣe laarin awọn eeyan.
- Ṣiṣenilojukokoro lori ki ọmọniyan maa ran ọmọ-iya rẹ lọwọ; torí pé iranlọwọ rẹ fun un saara ni.
- Ṣiṣenilojukokoro lori kiki janmọọn ati ririn lọ síbẹ̀, ati yiye awọn masalasi pẹlu ìyẹn.
- Ijẹ dandan ṣiṣe apọnle awọn oju-ọna awọn musulumi pẹlu jijina si nkan ti o le ṣe wọn ni ṣuta tabi ko inira ba wọn.