/ Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa

Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye pe dajudaju awọn ti wọn maa n kẹ awọn ti wọn yatọ si wọn, Ọba Ajọkẹ aye naa o kẹ wọn pẹlu ikẹ Rẹ ti o kari gbogbo nkan; ní ti ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). Lẹyin naa ni o wa pa aṣẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu kikẹ gbogbo nkan ti o wa lori ilẹ ni eeyan tabi ẹranko tabi ẹyẹ tabi nkan ti o yatọ si i ninu awọn iran ẹda, ati pe ẹsan iyẹn naa ni ki Ọlọhun kẹ wọn lati oke awọn sanmọ Rẹ.

Hadeeth benefits

  1. Ẹsin Isilaamu ẹ̀sìn ikẹ ni, ti gbogbo rẹ si duro lori itẹle aṣẹ Ọlọhun ati ṣiṣe daadaa si ẹda.
  2. Ọlọhun – ti O tobi ti O gbọnngbọn - Ọba ti O ni ìròyìn ikẹ lara ni, ati pe Oun – mimọ fun un – ni Ajọkẹ aye Aṣakẹ orun, ti O si maa n mu ikẹ de ọdọ awọn ẹru Rẹ.
  3. Iru iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan ti yio gba, nitori naa awọn ti wọn ba maa n kẹ eeyan Ọlọhun a kẹ awọn naa.