/ “Gbogbo dáadáa sàárà ni”

“Gbogbo dáadáa sàárà ni”

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Gbogbo dáadáa sàárà ni”.
Bukhaariy gba a wa ninu hadiisi Jaabir, Muslim gba a wa nínú hadiisi Huzaifah

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.

Hadeeth benefits

  1. Sàárà kò mọ lori nǹkan ti èèyàn n yọ jáde ninu dúkìá, bi ko ṣe pe o ko gbogbo oore ti ọmọniyan n ṣe tàbí sọ sínú, ti o si maa de ọdọ ẹlòmíràn.
  2. O n bẹ nibẹ isẹnilojukokoro lati maa ṣe dáadáa ati gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun ẹlòmíràn.
  3. Ki èèyàn ma fi ojú kere dáadáa kankan, kódà ki o kéré.