- Ọla ti n bẹ fun sùúrù ati ìdarí ẹ̀mí nígbà ìbínú, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ rere ti Isilaamu ṣe wa ni ojúkòkòrò si.
- Jija ẹ̀mí ni ogun nígbà ìbínú le koko ju jija ọ̀tá ni ogun lọ.
- Isilaamu yi agbọye agbára ni asiko aimọkan padà si awọn iwa alapọn-ọnle, èèyàn ti o ni agbara ju ni ẹni tí ó ni ikapa ìjánu ẹ̀mí ara rẹ.
- Jijina si ìbínú; tori ìnira ti o maa n fa fun ènìyàn kọ̀ọ̀kan ati àwùjọ.