- Ọla ti n bẹ fún ifẹ tó mọ́ kangá fun Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kìí ṣe ifẹ nitori anfaani aye.
- A fẹ ki a maa sọ fún ẹniti a nifẹẹ nitori Ọlọhun pé a nifẹẹ rẹ̀, kí ifẹ ati irẹpọ le maa lekun si.
- Ìtànkálẹ̀ ifẹ laarin awọn onigbagbọ ododo maa n fún ìjẹ́ ọmọ iya ninu ẹsin lagbara ni, ó sì maa n dáàbò bo awujọ kuro nibi tútúká ati pinpin yẹlẹyẹlẹ.