/ “Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”

“Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”

Láti ọ̀dọ̀ Jariir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti kii ba ṣàánú àwọn èèyàn, Ọlọhun ko nii ṣàánú rẹ, aanu ẹrú fún ẹ̀dá Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn okùnfà ti o tobi ju lati ri aanu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga gbà.

Hadeeth benefits

  1. Àánú, nǹkan ti a n fẹ ni fun awọn ẹ̀dá yòókù, ṣùgbọ́n wọn dìídì dárúkọ àwọn èèyàn ni ti akolekan pẹ̀lú wọn.
  2. Aláàánú ni Ọlọhun, O maa n ṣàánú àwọn ẹrú Rẹ ti wọn ni aanu, ẹ̀san maa n wa latara iran iṣẹ ni.
  3. Aanu àwọn èèyàn kó mímú oore de ọdọ wọn sínú, ati titi aburu kuro fun wọn, ati bíbá wọn lò pọ̀ pẹlu dáadáa.