- Gbigba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn jẹ́ ìpìlẹ̀ fun gbogbo oore, o si maa n jẹ ki oore wu èèyàn láti ṣe.
- Ikilọ kuro nibi awọn ìpalára ti ahọ́n maa n fà.
- Ẹsin Isilaamu, ẹsin ìfẹ́ ati apọnle ni.
- Awọn iroyin yii wa ninu awọn ẹka igbagbọ, ati ninu awọn ẹkọ ti a maa n yìn.
- Apọju ọ̀rọ̀ le wọ́ èèyàn lọ sibi nnkan ti a korira tabi nnkan eewọ, ọlà si n bẹ nibi ki èèyàn ma sọ̀rọ̀ àyàfi nibi dáadáa.