/ “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”

“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”

Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe: “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.
Muslim gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí a ba pade. O tọ́ fun Mùsùlùmí ki o ṣe ojúkòkòrò rẹ; tori ifi ara ro ọmọ-ìyá ti o jẹ Mùsùlùmí wa ninu ẹ, ati mimu ìdùnnú wọ inu rẹ̀.

Hadeeth benefits

  1. Ọla ti n bẹ fun ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, ati ẹ̀rín-músẹ́ ati ìtújúká ti wọn ba pade.
  2. Pípé sharia ati kikari rẹ, ati pe o wa pẹlu gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun awọn Mùsùlùmí ati ṣíṣe wọn ní ọ̀kan.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori ṣíṣe dáadáa kódà ki o kéré.
  4. A fẹ ki a maa dun àwọn Musulumi ninu; tori pe ìyẹn maa jẹ ki ìfẹ́ o wa laarin wọn.