Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igba...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni tí o ba gba aawẹ oṣù Ramadan ni ti igbagbọ ninu Ọlọhun, ati gbigba ìjẹ-ọran-anyan aawẹ ni ododo,...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa nipa ọla idide ni oru Laelatul Kọdri ti o maa n wa ni mẹ́wàá ikẹyin ninu oṣù Ramadan, ati pe ẹni...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọ...
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ...
Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhul Hijjah lọla ju awọn ọjọ ọdun yook...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii wo àwòrán ẹrú ati ara wọn, boya o rẹwà ni abi o burẹ́wà? Boya o tobi ni a...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."
Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ati jijagun si oju ọna Ọlọhun náà? O sọ pe: «Ati jijagun si oju ọna Ọlọhun, ayaafi arakunrin kan ti o jade pẹlu ẹmi rẹ ati dukia rẹ ti ko si ṣẹri pada pẹlu nkankan ninu rẹ».
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun".
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run” Wọ́n sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kí ni awọn nkan naa? Ó ní: “Ṣíṣe ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, pípidán, pípa eniyan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ, àyàfi pẹlu ẹ̀tọ́, jíjẹ owó èlé, jíjẹ owó ọmọ òrukàn, sísálọ ní ọjọ́ ogun ẹsin, ati jíju òkò ṣina mọ́ awọn obinrin abilékọ, onígbàgbọ́ ododo, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn”.
Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ".
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”.
Láti ọ̀dọ̀ Jubair ọmọ Mut'him- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe oun gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni tí ba n ja okùn ẹbí ko nii wọ alujanna”.