- Ṣíṣe leewọ pipa Al-Mu’aahad ati Adh-dhimmiyy ati Al-Mustahman ninu awọn alaigbagbọ, ati pe o jẹ ẹṣẹ nla ninu awọn ẹṣẹ ńláńlá.
- Al-Mu’aahad ni: Ẹni ti wọn gba adehun lọwọ rẹ ninu awọn alaigbagbọ ti o si n gbe ni ilu rẹ ti ko gbe ogun ti awọn Musulumi ti awọn naa ko gbe ogun ti i, Adh-dhimmiyy ni: Ẹni ti o sọ ilẹ̀ awọn Musulumi di ilu ti o si n san ìsákọ́lẹ̀, Al-Mustahman ni: Ẹni ti o wọ inu ilẹ̀ awọn Musulumi pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ fun asiko kan pàtó.
- Ikilọ kuro nibi jijanba awọn adehun pẹlu awọn ti wọn ko kii ṣe Musulumi.