- Jija okun ẹbí jẹ ọkan ninu awọn ẹṣẹ ńlá.
- Dída ẹbí pọ̀ maa wa ni ibamu si àṣà ni, o maa yatọ ni aaye kan si aaye kan, ati asiko kan si asiko kan, ati awọn èèyàn kan si awọn èèyàn kan.
- A maa n da ẹbí pọ pẹ̀lú ṣíṣe abẹwo, ati sàárà, ati ṣíṣe dáadáa si wọn, ati bibẹ aláìsàn wo, ati pipa wọn láṣẹ ṣíṣe dáadáa, ati kikọ fun wọn kuro nibi aburú, ati nǹkan ti o yatọ si ìyẹn.
- Bi ẹbí tí èèyàn já okùn rẹ ba ṣe sunmọ sí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe maa lágbára tó.