- Ẹṣẹ ti o tobi julọ ni mimu orogun mọ Ọlọhun; nitori pé O ṣe e ni eyi ti o gba iwaju ti o si tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nkan ti o n fi idi eleyii mulẹ ni gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe {Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.}.
- Titobi awọn ẹtọ awọn obi mejeeji, latari pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga so ẹtọ wọn mọ ẹtọ ti Ẹ.
- Awọn ẹṣẹ pin si awọn ẹṣẹ nla ati awọn ẹṣẹ kekere, ati pe awọn ẹṣẹ nla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti o ni ijiya ni aye, gẹgẹ bii awọn ijiya to ni odiwọn ati ègún, tabi adehun iya ọjọ ikẹhin, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ ti o tobi ipele ipele ni, ti apakan rẹ si nipọn nibi ṣíṣe ni eewọ ju apakan lọ, ati pe awọn ẹṣẹ kekere ni awọn ti o yatọ si awọn ẹṣẹ nla.