Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun maa n jowu, O si maa n binu O si maa n korira, gẹgẹ bi olugbagbọ naa ṣe maa n jowu, ti o si maa n binu, ti o si maa n korira, ati pe okunfa jijowu Ọlọhun ni ki olugbagbọ ṣe nnkan ti O ṣe ni eewọ ninu iwa ibajẹ gẹgẹ bii ṣìná ati ki ọkùnrin maa ba ọkùnrin lò pọ̀, ati ole jija ati ọti mimu, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ibajẹ.
Hadeeth benefits
Ikilọ kuro nibi ibinu Ọlọhun ati ifiyajẹni Rẹ nigba ti wọn ba fa ọgba awọn eewọ Rẹ ya.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others