- Bibura lori irọ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un; nitori lile koko ewu rẹ ati ẹṣẹ rẹ, bi ko ṣe pe ironupiwada ni o wa nibẹ.
- Wọn dárúkọ awọn ẹṣẹ nlanla mẹrin yii nìkan ninu hadiisi naa fun titobi ẹṣẹ wọn, kii ṣe pe àwọn nìkan naa ni ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà.
- Awọn ẹṣẹ pin si nlanla ati keekeeke, awọn nlanla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti ijiya ti aye n bẹ nibẹ, gẹgẹ bii ijiya ti sharia fi ààlà si, ati ègún, tabi adehun iya ti ọrun, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ nlanla ìpele ìpele ni wọn, awọn kan ninu wọn nipọn ju awọn kan lọ nibi jijẹ eewọ, awọn ẹṣẹ keekeeke ni awọn ti wọn yatọ si awọn ẹṣẹ ńláńlá.