- Ọla ti n bẹ fun iṣẹ oloore ninu ọjọ mẹwaa Dhul Hijjah, nitori naa o jẹ dandan fun Musulumi ki o ṣe amulo awọn ọjọ yii ki o si tun pọ ni iṣẹ oloore ninu rẹ, bii riranti Ọlọhun ti O lágbára ti O si tun gbọnngbọn, ati kika Alukurāni, ati ṣiṣe gbólóhùn "Allāhu Akbar", ati gbolohun "lā ilāha illā Allāhu", ati gbolohun "AlhamduliLlāhi, ati kiki irun, ati ṣiṣe saara, ati gbigba aawẹ, ati gbogbo awọn iṣẹ oloore yòókù.