/ “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”

“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa nipa ọla idide ni oru Laelatul Kọdri ti o maa n wa ni mẹ́wàá ikẹyin ninu oṣù Ramadan, ati pe ẹni ti o ba gbìyànjú ninu ẹ pẹ̀lú ìrun ati adua ati kika Kuraani ati iranti, ni ẹni tí o gba a gbọ́ ati ọla ti n bẹ fun un, ti o si n reti ẹsan Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.

Hadeeth benefits

  1. Ọla ti n bẹ fun oru Laelatul Kọdri, ati ṣisẹnilojukokoro lori idide ninu ẹ.
  2. Wọn ko nii gba àwọn iṣẹ olóore ayafi pẹ̀lú àníyàn òdodo.
  3. Ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ̀; tori pe ẹni tí ó bá dide ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.