Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé: "Etọ Musulumi lori Musulumi...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye diẹ ninu awọn ẹtọ Musulumi lori Musulumi ẹgbẹ́ rẹ̀, Àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni dídá salamọ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa g...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹnikankan o lee wọ alujanna ayaafi muumini, ati pe igbagbọ o lee pe ati pe ìṣesí awujọ m...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -: Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu...
Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Awọn iwa Isilaamu wo lo fi n lọla julọ? Ni o wa darukọ awọn iwa meji: Alakọkọọ: Pipọ ni i...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi ma...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi awọn saabe rẹ leere pe ṣe wọn fẹ ki oun tọka wọn si awọn iṣẹ ti o maa jẹ okunfa aforijin awọn ẹṣẹ, ati ip...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pe dajudaju Mumini, daadaa ni gbogbo ẹ, ṣugbọn Mumuni ti o ni agbara ninu igbagbọ rẹ ati ipinnu rẹ...

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé: "Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín".

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -: Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?" Wọn sọ pe bẹẹni irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ṣíṣe aluwala ni pípé lori ìnira, ati gbigbe igbẹsẹ pupọ lọ si mọsalasi, ati rireti irun lẹyin irun, ìyẹn ni ida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú".

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ, maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe ọ ni anfaani, ki o si tun wa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun, má si kagara, ati pe ti nkankan ba ṣẹlẹ si ọ, o ko wa gbọdọ sọ pe kani mo ṣe báyìí nkan báyìí báyìí ni ko ba jẹ, ṣugbọn sọ pe kọdarullāh wa maa sha'a fa‘al "akọsilẹ Ọlọhun ni, nkan ti O si fẹ ni O ṣe", tori pe (lao) "kani" o maa ṣina iṣẹ satani»

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Ad-Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a”.

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.

Lati ọdọ Anas – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: A wa ni ọdọ ‘Umar, o wa sọ pe: «Wọn kọ fun wa kuro nibi ifipaṣe-nnkan»

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ti ẹnikẹni ninu yẹn ba fẹ jẹun ki o yaa jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ti o ba si fẹ mu ki o yaa mu pẹlu ọwọ ọtun rẹ, dajudaju Shaitan maa n jẹun pẹlu ọwọ osi rẹ, o si maa n mu pẹlu ọwọ osi rẹ”.

Lati ọdọ Umar ọmọ Abu Salama- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo jẹ ọmọdekunrin ni abẹ itọju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ọwọ mi o si duro si oju kan ninu abọ, ni Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun mi pé: «Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ» Ìyẹn o wa yẹ ni ìṣesí ounjẹ mii lẹyin igba naa.