- Ninu awọn ẹkọ jíjẹ ati mimu ni didarukọ Ọlọhun ni ibẹrẹ rẹ.
- Kikọ awọn ọmọde ni awọn ẹkọ, agaga julọ ẹni ti o ba wa ni abẹ itọju eeyan.
- Ṣiṣe idẹkun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati gbigba aaye igbaaya rẹ nibi fifi imọ mọ awọn ọmọde ati kikọ wọn ni ẹkọ.
- Ninu awọn ẹkọ ounjẹ jíjẹ ni imaa jẹ ninu nkan ti o ba sunmọ eeyan, ayaafi ti o ba jẹ awọn iran orisirisi, nigba naa o le mu ninu rẹ.
- Idunnimọ awọn saabe pẹlu nkan ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ba fi kọ wọn, wọn mu iyẹn jade lati ibi ọ̀rọ̀ Umar ti o sọ pe: Ìṣesí mi o wa yẹ lori ìyẹn lẹyin igba naa.