- Wíwọ al-jannah ko lee maa bẹ ayaafi pẹlu igbagbọ.
- Ninu pipe igbagbọ ni ki musulumi o fẹ fun ọmọ ìyá rẹ nkan ti o n fẹ fun ara rẹ.
- Ṣiṣe fifọn salamọ ka ati wiwi i fún àwọn musulumi ni ẹtọ; latari nkan ti o wa nibẹ ni fifọn ifẹ ati ifọkanbalẹ ka laarin awọn eeyan.
- A ko ki n salamọ ayaafi si musulumi; fún ọrọ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe: "laarin yin".
- O n bẹ nibi imaa salamọ mimu ikọyinsi-ara-ẹni ati ibaraẹni-yan-odi ati ikunsinu kuro.
- Pataki ifẹ laarin awọn Musulumi ati pe dajudaju ninu pipe igbagbọ lo wa.
- O wa ninu hadīth miran pe dajudaju gbolohun salamọ ti o pe ni: "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu", a ti pe o ti to ki a sọ pe: "As salaamu alaykum ".