/ “Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”

“Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Ad-Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí ó bá dáàbò bo iyì ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lẹ́yìn ti ko jẹ ki wọn bu u tabi ṣe aburú si i, Ọlọhun maa dáàbò bo oun naa kuro nibi ìyà ni Ọjọ́ Àjíǹde.

Hadeeth benefits

  1. Kikọ kúrò nibi sísọ ọ̀rọ̀ tàbùkù iyì àwọn Musulumi.
  2. Ẹsan maa wa latara ìran iṣẹ, ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo oun naa kuro nibi iná.
  3. Isilaamu jẹ ẹsin mímú ara ẹni ni ọmọ-iya ati riran ara ẹni lọ́wọ́ láàrin àwọn Musulumi.