Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé: "Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye diẹ ninu awọn ẹtọ Musulumi lori Musulumi ẹgbẹ́ rẹ̀, Àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni dídá salamọ padà si ẹniti ó bá salamọ si ọ.
Ẹtọ keji: ṣiṣe abẹwo si alaaarẹ.
Ẹtọ kẹta: Títẹ̀lé ìsìnkú láti ilé rẹ̀ titi de àyè ikirun si oku lara, titi de ibi saare rẹ̀, titi tí wọ́n ó fi sin in.
Ẹtọ kẹrin: Dídáhùn ipepe bí ó bá pè é síbi àpèjẹ ìgbéyàwó àti awọn ǹkan mìíràn.
Ẹtọ karùn-ún: Ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín, iyẹn ni pe kí ó sọ fun un nigba ti ó bá ti sọ pe ALHAMDULILLAH lẹyin sínsín: YARHAMUKALLAH, lẹyin naa ni ẹniti ó sín ó sọ pe: YAHDIKUMULLAHU WA YUSLIHU BAALAKUM.
Hadeeth benefits
Titobi Islam nibi fífi ẹtọ rinlẹ laarin awọn Musulumi ati síso okùn ijẹ ọmọ-iya ati okùn ifẹ dáadáa laarin wọn.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others