- Ṣiṣe ojukokoro awọn saabe lori mimọ awọn iwa ti yio ṣe anfaani ni aye ati ọjọ ikẹyin.
- Sisalamọ ati fifunni l'ounjẹ wa ninu awọn iṣẹ ti o fi n lọla julọ ninu Isilaamu; latari ọla ti n bẹ fun un ati nini bukaata awọn eeyan si i ni gbogbo asiko.
- Ṣiṣe daadaa pẹlu ọrọ ati iṣe papọ pẹlu awọn iwa mejeeji yii, ati pe oun naa si ṣiṣe daadaa ti o fi n pe julọ.
- Awọn iwa yii nii ṣe pẹlu ajọṣepọ awọn Musulumi laarin ara wọn, awọn iwa kan ṣi wa ti o nii ṣe pẹlu ajọṣepọ laarin ẹru ati Olowo rẹ (Allāhu).
- Imaa bẹrẹ pẹlu salamọ jẹ ẹsa laarin awọn Musulumi, nitori naa wọn o gbọdọ kọkọ salamọ si keferi.