- Titayọ ara wọn awọn eeyan nibi igbagbọ.
- Nini ìfẹ́ si agbara nibi awọn iṣẹ; torí pé dajudaju yio maa ṣẹlẹ pẹlu rẹ anfaani ti ko le ṣẹlẹ pẹlu ikọlẹ.
- Ọmọniyan gbọdọ maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe e ni anfaani, ki o si fi nkan ti ko nii ṣe e ni anfaani silẹ.
- O jẹ dandan fun Mumuni ki o wa ikunlọwọ Ọlọhun nibi gbogbo alamọri rẹ, ki o si ma gbarale ara rẹ.
- Fifi akọsilẹ ati kadara rinlẹ, ati pe dajudaju ko tako ṣiṣe awọn okunfa ati gbigbiyanju nibi wiwa awọn nkan daadaa.
- Kikọ kuro nibi sisọ gbolohun «kani» ní ti ibinu nigba ti adanwo ba sọkalẹ, ati ṣiṣe ni eewọ titako idajọ ati akọsilẹ ti Ọlọhun.