“Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a”
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a”.
Muslim gba a wa
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀lẹ̀ ninu ọrọ ati ìṣe maa n lé àlámọ̀rí kún ni ẹwà ati pipe ati dídára, ohun ti o yẹ julọ ni ki ẹni ti ba n fi ẹ̀lẹ̀ ṣe nnkan o ri bukaata rẹ gbọ́.
Àìsí ẹ̀lẹ̀ maa n ko àléébù ba àlámọ̀rí ni, ko si nii jẹ ki èèyàn o ri bukaata rẹ gbọ, ti o ba wa ri bukaata naa gbọ, o maa jẹ pẹlu inira ni.
Hadeeth benefits
Ṣiṣenilojukokoro lori nini ìwà ẹ̀lẹ̀.
Ẹ̀lẹ̀ maa n ko ọ̀ṣọ́ ba ọmọniyan ni, oun si ni okunfa gbogbo oore nibi awọn alamọri ẹsin ati ayé.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others