/ “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”

“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin. O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.

Hadeeth benefits

  1. Ojuṣe onigbagbọ ododo ni ki o jẹ ki awọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun, ki o si maa ṣe wọn ni ojúkòkòrò lati ṣe rere.
  2. O tọ́ fun olupepe si ọdọ Ọlọhun ki o fi ọgbọ́n wo ọ̀nà ti yoo gba mu ipepe Isilaamu de ọdọ àwọn èèyàn.
  3. Ifunni ni iro ìdùnnú maa n bi ìdùnnú ati ìkọjúsí ati ifọkanbalẹ fun olupepe ati fun nǹkan ti o n fi han àwọn èèyàn.
  4. Ifi-ara-ni àwọn èèyàn maa n bi sísá, ati ìkọ̀yìnsí, ati mimu àwọn èèyàn maa ṣe iyèméjì nibi ọ̀rọ̀ olupepe.
  5. Gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, ati pe O yọnu si ẹsin kan ti o rọrùn fun wọn, ati ofin ti wọn ṣe ni irọrun.
  6. Ṣíṣe idẹkun ti wọn pàṣẹ rẹ naa ni ohun ti sharia mu wá.