- Pataki sisọ irun janmọọn ninu mọsalasi ati ifiye si awọn irun àti ṣíṣàì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà kúrò nibẹ.
- Didaa agbekalẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati mimu awọn saabe rẹ jẹ̀rán nigba ti o bẹ̀rẹ̀ fun wọn pẹlu ẹsan ti o tobi ni ọna ibeere, ati pe ọna yii wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ.
- Anfaani ti o n bẹ nibi ṣíṣe àfihàn ọ̀rọ̀ pẹlu ìbéèrè ati idahun ni: Ki ọrọ le wọni lọ́kàn gan-an nítorí kiko àìṣekedere pọ̀ mọ́ ìṣekedere.
- An-nawawi- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: FAZAALIKUMU-R-RIBAAT n túmọ̀ si: Ribaat ti a fẹ́, ipilẹ ribaat si ni ki èèyàn di nǹkan mú ṣinṣin, bii ìgbà tí o de ẹ̀mí ara rẹ mọ́lẹ̀ fun itẹle aṣẹ yii, wọn sọ pé: Òun ni o daa julọ ninu awọn ribaat gẹgẹ bi wọn ṣe sọ pe: Ijagun soju ọna Ọlọhun ni jija ẹ̀mí lógun, o si tun le túmọ̀ si ribaat ti o rọrun, o n túmọ̀ si pe: O wa ninu awọn oríṣiríṣi ribaat.
- Wọn paara gbolohun "Ar-Ribaat" wọn si so Alif ati Laam mọ́ ọn; ìyẹn jẹ igbetobi fun àlámọ̀rí awọn iṣẹ yìí.