“Ti ẹnikẹni ninu yẹn ba fẹ jẹun ki o yaa jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ti o ba si fẹ mu ki o yaa mu pẹlu ọwọ ọtun rẹ, dajudaju Shaitan maa n jẹun pẹlu ọwọ osi rẹ, o si maa n mu pẹlu ọwọ osi rẹ”...
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ti ẹnikẹni ninu yẹn ba fẹ jẹun ki o yaa jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ti o ba si fẹ mu ki o yaa mu pẹlu ọwọ ọtun rẹ, dajudaju Shaitan maa n jẹun pẹlu ọwọ osi rẹ, o si maa n mu pẹlu ọwọ osi rẹ”.
Muslim gba a wa
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ pe ki Musulumi maa jẹ ki o si maa mu pẹlu ọwọ rẹ ọtun, o si kọ kuro nibi jijẹ ati mimu pẹlu ọwọ osi; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pe Shaitan maa n jẹ o si maa n mu pẹlu rẹ.
Hadeeth benefits
Kikọ kuro nibi fifi ara wé Shaitan pẹlu jijẹ tabi mimu pẹlu ọwọ osi.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others