- Titobi akolekan Isilaamu si títún ìwà ṣe, ati pípé rẹ.
- Ọla ti n bẹ fun iwa dáadáa, titi ti ẹrú fi maa ti ara rẹ de ipo alaawẹ ti kii tú ẹnu, ati ẹni ti n dide fun ìjọsìn ni oru ti kii rẹ̀ ẹ́.
- Gbigba aawẹ ni ọsan, ati idide ni oru jẹ iṣẹ ńlá ti inira wa ninu ẹ fun ẹ̀mí, ẹni tí ó ni iwa rere de ipo àwọn méjèèjì tori jija ẹ̀mí rẹ lógun pẹ̀lú ibalopọ dáadáa.