- Hadiisi naa n tọka si ṣíṣe bíbú àwọn òkú ní eewọ.
- O n bẹ nibi gbígbé bibu àwọn òkú jù silẹ ṣiṣọ anfaani àwọn alààyè, ati mímú ojú to ààbò àwùjọ kuro nibi ọta ati ìkórìíra.
- Ọgbọ́n ti n bẹ nibi kikọ bibu wọn ni pe wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa; torí naa eebu wọn ko ṣe anfaani, ati pe sùtá wa nibẹ fun awọn mọ̀lẹ́bí rẹ ti wọn wa láàyè.
- Kò lẹtọọ fun ọmọniyan lati maa sọ nǹkan ti ko ba si anfaani ninu ẹ.