- Alaṣẹ obinrin jẹ majẹmu nibi nini alaafia igbeyawo, ti o ba waye laisi alaṣẹ obìnrin, tabi ti obìnrin ba fi ara rẹ lọkọ, igbeyawo naa ko ni alaafia.
- Alaṣẹ obinrin ni ẹni ti o sunmọ obinrin julọ ninu awọn ọkunrin, nitori naa alaṣẹ obinrin ti o jina ko lee fi i lọkọ pẹlu bibẹ alaṣẹ obinrin ti o sunmọ.
- Wọn ṣe ni majẹmu nibi alaṣẹ obinrin: Ijẹ ẹni tí o ti bàlágà, ati ijẹ ọkùnrin, ati imọna nibi mimọ awọn anfaani ìgbéyàwó, ki ẹsin alaṣẹ ati obìnrin jẹ bákannáà, ẹni ti ko ba ni awọn iroyin yii lara ko lẹtọọ si ijẹ alaṣẹ obinrin nibi tita koko igbeyawo.