- Ṣisẹnilojukokoro lori idunnimọ ibẹru, ati aiko akolekan pẹlu awọn nnkan adun aye ati ọṣọ rẹ.
- Ikilọ kuro nibi fitina obinrin, ninu wiwo tabi fifi ọwọ́ dẹngẹrẹ mú iropọ wọn pẹlu awọn ọkunrin ajoji, tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn.
- Fitina obinrin wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn fitina ni aye.
- Gbigba waasu ati gbigba ariwoye mu lara awọn ijọ ìṣáájú, ati pe nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si awọn ọmọ Ísírẹ́lì le ṣẹlẹ̀ si awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn.
- Fitina obinrin ti o ba jẹ iyawo, o le la bọ ọkùnrin lọrun ninu inawo ni nnkan ti ko lagbara rẹ, ti yoo wa ko airoju ba a lati wa awọn àlámọ̀rí ẹsin, ti yoo ti i lọ sibi fifi ẹmi ara rẹ̀ wéwu lori wiwa ayé, ti obinrin naa ba jẹ ajoji, fitina rẹ ni fifa oju awọn ọkunrin mọra ati iko iyẹgẹrẹ ba wọn kuro nibi ododo ti wọn ba ti jade ti wọn ba si ti ropọ mọ wọn, pàtàkì julọ ti wọn ba jẹ obinrin ti wọn kò bo ojú ti wọn si ṣira silẹ, eleyii le ja si ṣìná pẹlu awọn ipele rẹ, o wa tọ fun olugbagbọ lati dirọ mọ Ọlọhun, ati ifi erongba han si I nibi igbala kuro nibi wahala wọn.